Powered By Blogger

Subscribe Now: RSS feed

Friday, July 19, 2013

Yẹ̀yẹ́ Àwọn Aṣòfin Wa


Orísìírísìí ohun ẹlẹ́yàmẹ́lẹ́yá la ó máa rí nílú wa, Nàìjíríà. Ẹ ní kí ló dé? Ti ìwà ìbàjẹ́ àwọn 'arúfin' àbí aṣòfin ní wọ́n ń pera wọn ló mú mi kọ àròk yìí.

We witness various funny happenings in our country, Nigeria. Did you say why did i say so? It is the bad attitudes of our 'law breakers' or is it law makers prompted this essay.

Ẹ ò rí ìranù, ìwà àbùkù tí àwọn aṣòfin wọ̀nyìí ń dánwò, lójú ran ọmọ aráyé. Ọpẹ́lọpẹ́ òmìnira àwọn oníròhìn tòhun ẹ̀r ayélujára à bá má ti lánfààni láti rí yìí wo tàbí gbọ́ nípa rẹ̀ rárá. 

Can you see the nonsense our lawmakers are displaying in the viewing eyes of the world? Thank God for Press Freedom and the internet, we wouldn't have heard or seen this disgraceful act by our law makers.

<T ÀWÒRÁN YÌÍ KÍ ORÍ Yẹ̀Yẹ́ ÀWọN AṣÒFIN WA NÍ YORÙBÁ>

Bàbá ẹnìkan ló ń la irin mọ́ bàbá ẹlòmíràn lórí yìí, àfi bíi kó pa á, àfi bíi kókúkú kú dànù. Torí kíni, torí ipò, torí owó ìjókòó tabua tí wọ́n fi ń ṣara rindin. Ó ga o, àwọn ọmọ ìta ló ńṣòfin, ṣèlu fún wa. A tí ń rí àṣemáṣe nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ọpẹ́ díẹ̀, àmọ́ tí ìpínlẹ̀ Rivers yìí kọjá bẹ́ẹ̀. Ṣé bí yóó ṣe má a rí lọ rè é?

This is someone's father hitting a piece of metal on another person's father, he almost killed him. All for the post and the exorbitant sitting allowances. It's a pity, we have hooligans  as our lawmakers and rulers. We have been witnessing such mayhem in the houses of assembly but the case of Rivers State is beyond it. Is this how it will continue?

Àga ìjókòó la mọ̀ tí wn s lu ira wn bíi èdè-òyédè bá bẹ́ sílẹ̀ nínú ìpàdé wọn, nígbà mìíràn ẹ̀kẹ̀ṣẹ́ ni wọ́n fi ń fọ́ ra wọn lẹ́nu, ṣùgbọ́n tí ilẹ̀ Rivers tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kọjá àfẹnusọ.

We know of chair throwing during their meeting, and sometimes exchange of punches, but this Rivers crises is beyond chair throwing or punches.

Àwn Yorùbá ló spé, "bí a ṣé ń e nílẹ̀ wa, èwọ̀ ibòmíràn ni" bẹ́ẹ̀ ni ti orílẹ̀-èdèè wa erí, àwn jgúdújrá, bámúbámú ni mo yó mi ò mọ̀ pé ebí ń pa ọm nìkán àn kan ni òṣèlú tí a ní.

Yoruba said 'the way we do it in our land, differs from how it is been done somewhere else' thus is the Nigerian case, it is greedy rulers that we have.

Ta ni yóó wá ba wa túnlẹ̀ wa tò, ìkan ò gbé kan, irúkankan náà irúworúwo bẹ̀ gbẹ̀gìrì, oníjàgídíjàgan ló pọ̀ lára àwn adarí ìjba wa. Ijọ́ wo la ó ṣè yìí dà?.


Who will change our system for us? Our leaders are birds of a feather, when will shameful acts like this cease to occur?

Friday, June 28, 2013

World Ṣàngó Festival 2013



Ọba Ọ̀yọ́, ọba Làmídì Adéyẹmí kẹ́ta, n pè ọ́ sí ayẹyẹ ọdún Ṣàngó àgbáyé tí yóò wáyé nínú oṣù Ògún, tẹ ìpolówó òkè yìí kí ó darí rẹ.

Gbogbo yín lapé o!!!

The king of Ọ̀yọ́, ba Làmídì Adéymí 111 invites the world to the World Ṣàngó Festival in August, 2013. Click the above video to see the commercial.

Come one, come all!!!


Friday, June 14, 2013

Fi Èdè Yorùbá Kọ́ Ọmọọ̀ Rẹ (Teach Your Child Yorùbá Language)

Lánàá òde yìí, ẹgbẹ́ agbóhùnsafẹ́fẹ́ lédè Yoòbá pé ìpàdé àpérò, ìjíròrò ìṣe, àṣà Yorùbá, orí ọ̀rọ̀ ìjókó náà kò sì kọjá ohun tí a lè ṣe, ọ̀nà tí a lè gbà gbé èdè àṣà, ìṣe ìbílẹ̀ wa lárugẹ. 


The Yorùbá Broadcasters Association, Lagos state organized a seminar on reviving the Yorùbá language in our homes.


Ọ̀pọ̀ ọmọ Yoòbá àtàtà, àwọn lọ́balọ́ba, èèyàn jànkàn-jànkàn ló péjọ síbi ìpàdé yìí láti gbé àṣà baba-ńláa wa ga. Àwọn àgbàgbà bíi baba Ẹlẹ́buìbọn, ògbóntàgi ọ̀yàwòrán èré orí-ìtàgé Túndé Kìlání, olóyè Gàní Adams àti àwọn ọmọ Yorùbá réré l'ó péjúpésẹ̀. Wọ́n ṣa àwọn òbí láì yọ̀ alágbàtọ́ sílẹ̀ lábẹ ọ̀rọ̀, wọ́n wí fún wọn pé ó kúdíẹ̀káàtó kí ọmọ káàárọ̀-o-ò-jíire málè fọ èdè bàba rẹ̀. 


Various sons and daughters of Yoruba land were in attendance; Lai Mohammed, Tunde Kilani, Yemi Elebuibon, Gani Adams and others.


Ìwádí fi hàn pé bí ó ba e díẹ̀, èdè Yorùbá a pare, k'Èlédùà máj a ríi.  Lá ní láti fwọ́sowọ́pọ̀ wá nǹkan e kí èdè wa má báa gb bí i odò, kí a má gbàgbé orísun wa.

Researchers claim that in years to come, the Yoruba language will be extinct. We must therefore collectively endeavour not to let it die.

Àfi kọ́mọ Yoòbá máà f'èèbó bi ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀. Alàgbà Láì Mòhammẹ̀d ti ẹgbẹ́ òṣèlú ACN pàápàá gbà àwọn òbí nimọ̀ràn láti fi èdè, àṣà ìṣe ilé wa kọ́, tọ́ àti wo àwọn èwe wa torí àwọn ọmọ wọ̀nyí ni yí ó kù nílé bí àgbà ilé bá filẹ̀ ṣaṣọ bọra, àwọn ni kò ní jẹ́ kílé dahoro. 


Instead of speaking more in Yoruba, our children speaks English than the former, whereas some don't even know how to speak because their parents do not teach or speak with them in Yoruba language. Chief Lai Mohammed implored parents to speak and teach the Yoruba culture to their wards.

Torí náà, ó ṣe kókó, ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ àti àrọ́mọdọ́mọ wa gbọ́ Yoòbá kí èdè baba ńláa wa Oòduà, Ọ̀rànmíyàn, àti àwọn àgbàgbà ilẹ̀ kú-oótù-oòjíire má bá à di ohun ìgbàkánnì, ohun ìgbàgbé, òyìnbó là á ńtẹ̀lé gọ̀ṣúgọ̀ṣú a gbàgbé pé a kí í ṣe òyìnbó a si le dabi won. 

Chinua Achebe has said, "my people no longer act as one..." why? because things has fallen apart, we all want to act and be like the whites neglecting the real-self whereas this is not possible. We should stop following them like zombies.

Ọ̀rọ̀ yìí kànwá gbògbògbò, ó kandandan kí ọmọ Odùduà mọ òwe, ìṣe, iṣẹ́ àti gbogbo nǹkan tó rọ̀mọ́ àṣà Yorùbá. A kúkú ní báwọn wí bíkòṣe àwọn òyìnbó ọlọ́gbọ́n àrékéreké tí ó sa gbogbo ipá láti pa ìran Yorùbá rẹ́ lórílẹ̀-èdè ayé. Àti pé, ó yẹ kí ilé-ìwé máà fi èdè àbínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ́ọ̀ọ́ láti jẹ́léósimi alákọ̀bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì, èyí á jẹ́ kí akẹ́kọ́ọ̀ọ́ mọ ìgbéayée wọn gẹ́gẹ́ bí alágbẹ̀dẹ ṣe mọ Ògún.  

Brethren, it is our responsibility as bonnafide sons and daughters of Oduduwa to train our child in the way of the Yorùbá culture and tradition. The educational curriculum should accommodate teaching all subjects, courses in Yorùbá language from elementary to higher institution.

Toò, tèmi tìrẹ, m Oòduà tkàntkàn, ìṣẹ̀ṣe làgbà, ọmọàlè ní ń f'ọwọ́ òsì júwe ilé Bàbá rẹ̀, kí Yorùbá má bàá kú dọwọ́ wa ooooo!!!  

To this end, tradition is key and paramount, only a bastard points to his father house with his left hand. True sons of Oòduà, the onus lie on all Yorùbá to keep the Yorùbá heritage alive for the future generation.


Do you understand Yorùbá? Do you speak it well? Watch this little girl as she speaks the Yorùbá language Fi Èdè Yorùbá Kọ́ Ọmọọ̀ Rẹ

Click and subscribe - www.youtube.com/yobamoodua 


eun :)

Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.

Tuesday, June 11, 2013

Mọ̀SHOOD KÁṣÌMÁAWÒÓ ỌLÁWÁLÉ ÀBÍọ́LA - OGUN ỌDÚN (June 12, 1993)

 On the 12th of June 1993, Moshood Kasimawo Olawale Abiola contested for the post of the Nigerian Presidency under the Social Democratic Party (SDP) which he won but his election was annulled and the count was given to someone else. 

This decision by the powerful ones in government led to an uproar in the cities especially in Lagos State, i can remember that rogues burning tires and causing mayhem snatched my mother's handbag.

Later, the news was everywhere that MKO has been arrested and detained in prison. 1998, five years after, we heard the sad news that our own Moshood Kasimawo Olawale gave up the ghost. 

It was believed that MKO was killed by the government, by those who forgot that one day they will also die. 

Abiola was one of the warriors who fought for democracy in Nigeria. 

May he rest in peace and may God guide, protect those alive.

Amen.

Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.