Orísìírísìí
ohun ẹlẹ́yàmẹ́lẹ́yá la ó máa rí nílú wa, Nàìjíríà. Ẹ ní kí ló dé? Ti ìwà ìbàjẹ́
àwọn 'arúfin' àbí aṣòfin ní wọ́n ń pera wọn ló mú mi kọ àròkọ yìí.
We witness various funny happenings in our country, Nigeria.
Did you say why did i say so? It is the bad attitudes of our 'law breakers' or is it law makers prompted this essay.
Ẹ ò rí ìranù, ìwà àbùkù tí àwọn aṣòfin wọ̀nyìí ń dánwò, lójú
ran ọmọ aráyé. Ọpẹ́lọpẹ́ òmìnira àwọn oníròhìn tòhun ẹ̀rọ ayélujára à bá má ti lánfààni láti rí yìí wo tàbí gbọ́ nípa rẹ̀
rárá.
Can you see
the nonsense our lawmakers are displaying in the viewing eyes of the world?
Thank God for Press Freedom and the internet, we wouldn't have heard or seen
this disgraceful act by our law makers.
<Tẹ ÀWÒRÁN YÌÍ KÍ ORÍ Yẹ̀Yẹ́
ÀWọN AṣÒFIN WA NÍ YORÙBÁ>
Bàbá ẹnìkan ló ń la irin mọ́ bàbá ẹlòmíràn lórí yìí, àfi
bíi kó pa á, àfi bíi kókúkú kú dànù. Torí kíni, torí ipò, torí owó ìjókòó
tabua tí wọ́n fi ń ṣara rindin. Ó ga o, àwọn ọmọ ìta ló ńṣòfin, ṣèlu fún wa. A
tí ń rí àṣemáṣe nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ọpẹ́ díẹ̀, àmọ́ tí ìpínlẹ̀ Rivers yìí kọjá
bẹ́ẹ̀. Ṣé bí yóó ṣe má a rí lọ rè é?
This is
someone's father hitting a piece of metal on another person's father, he almost
killed him. All for the post and the exorbitant sitting allowances. It's a
pity, we have hooligans as our lawmakers
and rulers. We have been witnessing such mayhem in the houses of assembly but
the case of Rivers State is beyond it. Is this how it will continue?
Àga ìjókòó la mọ̀ tí wọn sọ lu ira wọn bíi èdè-òyédè bá bẹ́ sílẹ̀ nínú ìpàdé wọn, nígbà mìíràn ẹ̀kẹ̀ṣẹ́ ni wọ́n fi ń fọ́ ra wọn lẹ́nu, ṣùgbọ́n tí ilẹ̀ Rivers tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kọjá àfẹnusọ.
We know of chair
throwing during their meeting, and sometimes exchange of punches, but this
Rivers crises is beyond chair throwing or punches.
Àwọn Yorùbá ló sọpé,
"bí a ṣé ń ṣe nílẹ̀ wa, èwọ̀ ibòmíràn
ni" bẹ́ẹ̀ ni ti
orílẹ̀-èdèè wa ṣerí, àwọn jẹgúdújẹrá, bámúbámú ni mo yó mi ò mọ̀ pé ebí ń pa ọmọ ẹnìkán àn kan ni òṣèlú tí a ní.
Yoruba said 'the way we do it
in our land, differs from how it is been done somewhere else' thus is the
Nigerian case, it is greedy rulers that we have.
Ta ni yóó wá ba wa túnlẹ̀ wa tò, ìkan ò gbé kan, irúkankan náà irúworúwo ọbẹ̀ gbẹ̀gìrì, oníjàgídíjàgan ló pọ̀ lára àwọn adarí ìjọba wa.
Ijọ́ wo la ó ṣè yìí dà?.
Who will change our system for
us? Our leaders are birds of a feather, when will shameful acts like this cease
to occur?
No comments:
Post a Comment
Kí ni o ní sọ?