Monday, December 15, 2014

Láyée Ọyẹ́




Ní kété tí a bá ti wọ ìkẹwàá ọdún ni afẹ́fẹ́ ọyẹ́ á ti máa fẹ́ lu 'ni lára díẹ̀ díẹ̀. 

Láyée ọyẹ́, ààjìn ni ọyẹ́ ti ń jáde, fẹ̀ẹ̀rẹ̀ ò kí ń ṣe é kó, òtútù ọyẹ́ a máa mú kí oorun rọ 'ni lọ́rùn gidi gan-an ni. Àgbàlagbà yóò ká rúgúrúgú, ọmọdé náà a sùn á kásẹ̀ worobo bíi ọmọ ìkókó. 

Ní ìdájí, bí ilẹ̀ bá mọ́, kùrukùru funfun á bo ojúu sánmọ̀ mọ́lẹ̀ gùdù, a lè má fẹ́ẹ̀ rí ẹni ńbọ̀ níwá, a ó ti kò ó tán kí a tóó kó fìríi rẹ̀. 

Láyée ọyẹ́, a kì í pẹ́ kan lọ títí ní balùwẹ̀, kíá mọ́sá ni à ń rọ́ omi sára, wàrà seṣà à ń bóóde nílé-ìwẹ̀. Gbígbọ̀n ni ẹní bá rẹ̀pẹ̀tẹ̀ sí ibalùwẹ̀ yó máa gbọ̀n nígbàtí atẹ́gùn tútù bá rọ́ síi lára. Oótù ní kínkankíkan ojúmọ́, láyée má f'omi wẹ̀ kan 'ra. Àwọn ọ̀bùn a máa fi omi b'ọ́jú ni, wọ́n sì lè ṣan'pá ṣan'sẹ̀ kí wọ́n bọ́ sí'gboro. 

Àfi bíi ẹni pé ilé iṣẹ́ẹ elùbọ́ làwọn ọmọ elòmíràn ti ń ṣíṣe ni, ara wọn á funfun. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ara rẹ̀ funfun ni a máa ń sọ fún wípé ọyẹ́ ti gbé lọ nítorí àwọ̀ọ ti di ti ọlọ́yẹ́.

Òrí ni ìyáà mi fi tọ́ mi. Láyée ọyẹ́, ni a ma fi ń pa ara, t'ára yóò máa dán gbinrin, ara ò jẹ́ mọ ọyẹ́. 

Láyée ọyẹ́, tí ètèe elétè yóò máa bẹ́, títa ńkọ́? Ní ayée ọyẹ́ tí àtẹ́lẹ́-ọwọ́ pẹ̀lú ti ẹsẹ̀ yóò máa sun omi jáde. 

Láyée ọyẹ́, tí èfúùfù ọ̀gìnìtìn yó máa fẹ́ yìì, yàà, á máa fẹ́ yòò, oòrùn  gbígbóná yẹn náà a máa jó 'ni lára fofofo ní kíjankíjan. 

Àkókò tí ereku á gba'lé gba oko. Ekuru lóríi bíi ewú, nínú ihò-imú, ihò-etí, pàntí nínú ojú. Àkókò ikọ́, ọ̀fìnkìn ni ìgbà ọyẹ́ jẹ́ fẹ́lòmíì láyée ọyẹ́. 

Láyée ọyẹ́, igi oko gan-an alára mọ̀ pé ọyẹ́ ń mú, ewé á wọ́n lóríi igi, kí ni ìràwé? Pápá oko a máa dùn ún jó nínúu ọyẹẹ́ pọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ewu inúu ọyẹ́ pọ̀ jọjọ. Ọ̀gbẹlẹ̀ ni àsìkòo ọyẹ́, iná a máa ràn fòò nínúu ọyẹ́, òwe kan ní "... ó ràn bíi (ináa) pápá inú ọyẹ́. 

Láyée ọyẹ́, ẹní bá kó sí aṣọ t'ó nípọn láàárọ̀ ni ooru baba ooru yóó bá fín 'ra lọ́ọ̀sán ganrínganrín. Wéré lọ́wọ́ kan ni ohun a bá sá (aṣọ, oúnjẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) ń gbẹ hánhán láyée ọyẹ́. 

Láyée ọyẹ́ tí ooru á máa bá ẹnu yọ bí a bá ń s'ọ́rọ̀. Òjò ọyẹ́ la mọ òjò t'ó bá rọ̀ lóṣù kankànlá ọdún sí, tí ọyẹ́ á sọ̀kalẹ̀, t'áfẹ́fẹ́ ọyẹ́ yóò máa ya lu teranko t'ènìyàn. 

Lógún ọdún sẹ́yìn, ìyẹn láyée ọyẹ́ ni mò ń ròhìn, láyée ọyẹ́ nígbàtí ọyẹ́ ń mú, láyée ijọ́hun t'ọ́yẹ́ wà. Láyée ọyẹ́, inú á máa dùn pé ọdún ti parí, titun fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀. 

Ọyẹ́ wáá dà báyìí o? 

Àbí torí pé igbó Èkó ayée ọyẹ́ ti di ìgboro ni? 

Ní ìgbèríko alára, ọyẹ́ tí à ń wí yìí ò fi bẹ́ẹ̀ sìí,  kò dàbíi ti ayée ìgbà kan. Ọyẹ́ẹ̀ mi ọ̀wọ́n, è é ṣe? È é ti rí? Níbo lo wà a?


Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.
https://ssl.gstatic.com/ui/v1/icons/mail/images/cleardot.gif