Monday, December 30, 2013

New Year Resolution; Ta Ló Ń Pa Á Mọ́


Ìpinnu Ọdún Tuntun

Bitter kola grows every year, walnuts are annually, also are kola nuts found yearly. So is the new year resolution this days.

Ọdọọdún là ń rórógbó, ọdọọdún là ń r'áwùsá, bẹ́ẹ̀, ọdọọdún là ń bá ọmọ obì lórí àtẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ti ìpinnu ọdún tuntun jẹ́ láyé òde òní.

In churches, new year resolution is a requisite as we approach a new year.

Ní ṣọ́ọ̀ṣì, tipá ti túláàsì ni ìpinnu ọdún tuntun bí a bá ti fẹ́ mú ọdún tuntun. 

Kí wá ni ìpinnu ọdún tuntun ní pàtó? Ìpinnu ọdún tuntun ni ìlànà ìṣe, iṣẹ́, ìgbésẹ̀ àti ìwùwàsí tí ènìyàn fẹ́ẹ́ tọ̀ nínú ọdún tuntun. 

What is new year resolution? New year resolution is the procedure, work, steps and behaviour that one intends to follow in the fresh year.


Ìpinnu ọdún tuntun dà bíi ìwé àtọ́sọ́nà a sì lè pè é ni àkọmọ̀nà fún ọdún tuntun. Bóyá láti jáwọ́ nínú ìwà pálapàla kan ni, ṣe àtúnṣe àṣemáṣe tàbí láti bẹ̀ẹ̀rẹ iṣẹ́ tuntun kan ni, èyí ni àtọ́sọ́nà tí a mọ̀ sí ìpinnu ọdún tuntun.

New year resolution could be compared with a master plan, we can also call it watchword for the new year. Whether to halt a bad habit, remedy a mistake, this is the master plan known as new year resolution.

Ọdọọdún sì làkọmọ̀nà ma ń yípadà, tọdún nìí yàtọ̀ sí tèṣì, bẹ́ẹ̀ ni tọdún yìí kò lè jọ tọdún tó ń bọ̀. Tèní ò jọ tàná ni. Àmọ́ ṣá, mélòó ń'nú wa ló ń pa ìpinnu ọdún tuntun ọ̀hún mọ́?


Watchword changes yearly, this year's own is different from the previous year, also this year's revolution  or watchword will not be the same as next year's own. Today's is not same as tomorrow's. But, how many among us keep our resolutions?

Ibi tí a ti sọ ọ́ ló mọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn mìíràn sì gbìyànjú di bíi oṣù méjì sí mẹ́ta kí wọ́n tó ju ọwọ́ ìpinnu tuntun sílẹ̀ tí wọ́n bá tiwọn lọ. Ìwọ ń tìẹ, ọmọ pupa lo yàn láàyò, ní ti eré oríi bẹ́ẹ̀dì, ọ̀gá lọ̀gáa Múdà ńjẹ́. 

It all ends where it was said, some were dogged, tried it for two to three months before they let go the resolution. You, its fair ladies you like to date, for the bed game, the master of the game you are.

O ní o kò ní gbé obìin mọ́ lọ́dún tuntun, "ó jẹ́ pupa o, ó jẹ́ dúdú o, n ò jẹ́ tún padà sínú ìwà àbùkù." Kò pẹ́ kò jìnà nínú ọdún tuntun, kàkà kó sàn lára ìyáa àjẹ́, ọmọge dúdú àti pupa dáràn lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n jagunlabí agbẹ́nu lé gàná. 

You said you will stop promiscuity in the new year, "if its fair, if its dark, i will not return to immoral attitudes." Still early in the new year, instead of sticking to the gun, all the ladies are in trouble.

Ǹjẹ́ ìwọ pa ìpinnu ọdún tuntun jẹ rí?
Àbí ìwọ tẹ̀lẹ́ ìpinnu ọdún tuntun láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọdún dé ìparí? Nínú ìṣe, ìwùwàsí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí o kó sínú ìpinnu ọdún tuntun rẹ, ó tó mélòó to mú di múmúṣẹ? 

Do you keep your new year resolution?
Or you abide by the new year resolution from the beginning of the year to the end? 
In manners, attitude and many more in your new year resolution, how many did you bring to fruition?

O ní igi cìgá méjì ló fẹ́ máa mu lóòjọ́ lọdún tuntun, o gbìyànjú fún oṣù kan, nígbà tí ó di oṣù kejì, ìpinnu ọdún ti yẹ̀, cìgá fífàa rẹ̀ lóòjọ́ ti kọjáa iye tí ó ń fà tẹ́lẹ̀.

You claimed to smoke a stick of cigarette daily, you tried for a month, in the next month, the new year resolution has been abandoned, your daily cigarette intake have increased than what you consume before.

Ní ìmọ̀ràn kékerée tèmi, ò bá dára ko wẹ̀yìn wò kí o mọ ibi tí bàtà ti ń ta ọ́ lẹ́sẹ̀, tí o ti ṣì ṣe tàbí tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀, kí o sì kọ ọ́ sílẹ̀.

In my little opinion, it will be nice to know where the shoe itches, where you have done wrong, and write it down.

Lẹ́yìn èyí, ṣe ìpinnu ọ̀hún tí o fẹ́ mú ṣẹ lọ́dún tuntun, kọ̀yí náà sílẹ̀ pẹ̀lú. Mú ìgbà tí o lérò wípé ìpinnuù rẹ á di múmúṣẹ, kọ̀yí sílẹ̀ bákan náà. Gbọ́ o, kíkọ àwọn ìgbésẹ̀ rẹ sílẹ̀ nìkan kọ́ o, gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ bá ìpinnuù rẹ.

After this, make a resolution on what you want to achieve in the new year, write this down also. Pick a date/time to achieve your plan, write this down as well. Listen, it is not only writing down this plans but ensuring it is brought to fulfillment.

Àyà fi Olúwa nìkan ló lè ràn wá ṣe ní ti ìpinnu ọdún tuntun dé, torípé ṣàṣà ènìyàn ló ń pa á mọ́. Àbí irọ́ ni? Kíni ìpinnu ọdún tuntun ùn rẹ fún ọdún un #2014?

Only God can help us all with new year resolution, because virtually everyone of us fail to keep our resolutions. Or is it a lie? What is your new year resolution for the year #2014) 


YOUTUBE
TWITTER

Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.

Tuesday, December 24, 2013

Mo dúpẹ́ (Am Grateful)

Mo dúpẹ́.
Am grateful.

Ọlọ́run ùn mi Ọba Òkè, ògo ni fún orúkọ Elédùmarè Ọba Adániwáyé mágbàgbé ẹni. 

Ǹjẹ́ bàbá modúpẹ́ lọ́ọ̀rẹ, ọpẹ́ ìmọ̀, ọgbọ́n, òye tí Ẹ jogún fún mi, modúpẹ́. 

Modúpẹ́ àǹfààní tí O fún mi láti gbé Yobamoodua kalẹ̀, mo sì dúpẹ́ pé ẹ̀mí wà, bí ẹ̀mí bá sì wà, ìrètí ń bẹ. 

Ọ̀báńjígì gba ọpẹ́ẹ̀ mi, modúpẹ́.

My God, the Almighty, glory be thy name, the One who created human to live on earth. Father, i thank you, thank you for the knowledge, wisdom and understanding that you have given to me, I thank you. Thank you for the opportunity that given me to create yobamoodua, am also grateful for life, when there is life there is hope. God Almighty accept my thanksgiving.

N ò jẹ́ gbàgbẹ́ ìyáà mi ọ̀wọ́n, abiamọ-a-bọ̀já-gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ, a-tátí-were-sẹ́kún ọmọọ rẹ̀, ìyá rere, mo dúpẹ́ o. Bí kò sí ti ìmọ̀ràn, ìlàlọ́yẹ̀e èdè, àṣà Yorùbá tí ẹ là mí, tani n ǹ bá tọ̀. Ẹ ṣeun modúpẹ́.


I didn't forget my dear mother, a mother that back snuggle her child always, a woman that responds fast to the cry of her child, I thank you. If not for your advice, breakdown of Yorùbá language and culture, who would I have approached. Thank you, am grateful.

Google, ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára, ilé-iṣẹ́ẹ yín káà jóná, modúpẹ́ gidi gan-an fún àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín. 


Google, the internet giant, your company will not be engulfed by fire, am very grateful fro your workshops and lectures.

Ọ̀gbẹ́ni Kelvin Scandel, òyìnbó olólùfẹ́ èdè àgbáyé, kú iṣẹ́ o. Modúpẹ́ àǹfààní tí o fún mi láti ṣe ògbufọ̀ abala èdè Yorùbá lórí ibùdó ìtàkùn àgbáyée indigenoustweets, inú mi dùn wípé èmiì rẹ daṣẹ́pọ̀. O ṣe é modúpẹ́.

Mr. Kelvin Scandel, white man who loves the world's language, well done. I am grateful for the opportunity of translating the Indigenoustweets Yorùbá section website.

Ẹniì mi Bassey aláṣẹ radio tó ń gbéṣe Yorùbá lárugẹ lórí ayélujára Distinct Radio, modúpẹ́ pé a mọra. 

My person, Bassey the director of @Distinctradio, an online radio station that promote Yorùbá culture, am glad we know each other.

Jummy, obìrin bí okùnrin olùdaríi NigerianBlogAwards, o ṣeun modúpẹ́, ire ni tiwa. Òní ló pọ́dún kan tí a ṣe ìfilọ́lẹ̀ Yobamoodua, ọpẹ́ púpọ̀ lọ́ọ́ọ gbogbo afẹ́ni fẹ́re, ẹnikẹ́ni tí ó ti bá yobamoodua ṣepọ̀ ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, gbogbo yín lẹ ṣeun.

Jummy (@goodnaijagirl) a woman like man, the director of #NigerianBlogAwards, thank you, am grateful.

Ẹ̀yin tèmi lọ́kùnrin lóbìrin àtọmọdé pẹ̀lú àgbà, ẹni modárúkọ àti ẹni tí mo ò dárúkọ, n ò kúkú ṣààta ẹnìkan, gbogbo wa pátá la ó kérè oko délé koko, e ṣe é, ẹ kú ifẹ́ tí ẹní sí Yorùbá, bí ò sẹ́yìn, ta lèmi? Modúpẹ́ lọ́wọ́ọ yín pé àjọṣe wa láti ọdún kan sẹ́yìn sì ń gún régé, á tú bọ̀ máa dára síi ni. Á júṣe fún un yín, O'òduà á gbè yín, ẹ ò ní fẹnu gbó bí ọwọ́, ire wa yóó tẹ̀wá lọ́wọ́ láìpẹ́ ọjọ́, torípé kíákíá ni kìnìún-un lẹ́ranbá, kíákíá nire yín yóò dé, tí iṣẹ́ẹ yín yóò yorí sí rere. 

My friends, men, women, young and old, the ones i mentioned by name and those i did not mention, i do not ridicule anyone, we will all be fruitful, thank you for the love you all have for the Yorùbá heritage, if not for you guys, who am I? Am grateful for the mutual understanding in the last one year, may it continue to be fruitful. It will be well with you, Odduwà will be with you, you will not regret, our blessing will be ours soon, because the lion runs fast to attack a prey, so will our blessings come to us fast, and our work will yield good fruit.

Ẹ ṣeun modúpẹ́, a sì kú ọdún, à ṣèyí ṣe ọ̀pọ̀ọ rẹ̀ láyé.

Thank you am grateful, merry Xmas and Happy New Year, we will witness more years.

Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.

Thursday, November 28, 2013

Ewì Ọmọge Ìwòyí - Girls of now-a-days





mọge ìwòyí o!!!
ẹ̀yin ni mò ń báwí, ẹ t’ẹ́tí kí  gb’ọ́rọ̀ nuù mi
Ẹ yáa gbọ́ mi yéké.
Àntí Bùkọ́lá, Tọ́sìn o lẹ́sẹ̀ tínínrín
Sììstá Jẹ́nífà lẹ́sẹ̀ pàlàbà, Fásílá o lẹ́sẹ̀ ẹe,
Àfi kí ẹ tọ́jú ki e tọ́tè, máa gbọ̀ndí kiri àdúgbò
Áwù, aṣ kù lọ́jà, èwo ni ti bóńfòèwo n taṣ pénpé kí ẹ dá,
Kò balẹ̀ le fi e
À ẹ ò mọ̀ pé aṣ àbúròo yín l wọ̀?
Ìbàdí ọmọge yín là ń wò l’òfẹ́ lófò,
Gbogbo ọmú rè é níta,  jọ̀wọ́  bòdíi yín o, ó ti súu wá í wò.
Níbi tí bùbá àti ìró tó gbáfẹ́ gbé wà,
Àmọ́ àkísà lẹ̀yín yàn láàyò.
Gbogbo ibi la ti ń bá ọ, bíi ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀
Ìwọ lónìí, ìwọ lánàá bí kún apọkọj
Wàá gbé dúdú, gbé pupa,
Bo ń gbé kúkúrú lò ń gbé gíga
Àti ọ̀dọ́ àt’ọkọ ilé, déédé ni
Ṣé kò kí ń rẹ̀ ọ́ ni? Ó rẹ̀ mí tì, é le è rẹ̀ mí lo fi ń e
Àtolátọ̀sí, àtoní wárápá, gbogbo wọn ló ń ebẹ̀,
ò kọ̀ kan, gbogbo ayé ní í gbé e sẹ́nu, kò yàtọ̀ sí síbí ilé ìjun
Àlàpà tó dnu ílẹ̀ran oríi ní í fi bẹ̀ e ‘lé
Tára bá bájẹ́ talára ní í dà, bí ọ̀rọ̀ àgbà
Ṣọ́ ọ e ọmọge fácitì, ìwọ ọmọ ilé ìwé gíga  ṣọ́ra e
Alágmọ ti bímọ, àìmọ́jó dọwọ́ọ yín 


The above ewì (a Yorùbá poem) talks about the indecent dressing among-st girls of now a days - ìwọ̀ kuwọ̀ láàríàwmọge ìwòyí

We look at western culture, imitate them and forget our own - àà òkèèrè là ń kọ́ e, tí a gbàgbée tiwa

We wear clothes worn by club strippers on the street - aṣ ilé ijó là ń wọ̀ kiri ìgboro

We no longer wear our Yorùbá attires (ò w aṣ ìbílẹ̀ wa mọ́). Prostitution and promiscuity is the other of the day - àgbèrè àti panágà ti gbàlú kan.


See the translation of the ewì below :


mọge ìwòyí o!!!
Pretty girls of now a days!!!

ẹ̀yin ni mò ń báwí, ẹ t’ẹ́tí kí  gb’ọ́rọ̀ nuù mi
Yes it is you am talking to, listen to my voice

Ẹ yáa gbọ́ mi yéké.
Better listen to me clearly.

Àntí Bùkọ́lá, Tọ́sìn o lẹ́sẹ̀ tíírín
Aunty Bùkọ́lá, Tọ́sìn the tiny leg

Sììstá Jẹ́nífà lẹ́sẹ̀ pàlàbà, Fásílá o lẹ́sẹ̀ ẹe,
Sister Jenifa the big leg, Fasilat the hen leg,

Àfi kí ẹ tọ́jú ki e tọ́tè, máa gbọ̀ndí kiri àdúgbò
All you know is to paint your eye and lips, shake ass about

Áwù, aṣ kù lọ́jà, èwo n bóńfòèwo laṣ pénpé kí ẹ dá,
When there are clothes in the market, which one is this short, small cloth that you wear,

Kò balẹ̀ l fi e
Not long enough

À ẹ ò mọ̀ pé aṣ àbúròo yín l wọ̀?
Or you don not know is your sister's?

Ìbàdí ọmọge yín là ń wò l’òfẹ́ lófò,
We see the waist of a beauty free of charge,

Gbogbo ọmú rè é níta,  bòdíi yín o, ó ti súu wá í wò.
The breasts are out, cover it, we are tired of looking.

Níbi tí bùbá àti ìró tó gbáfẹ́ gbé wà,
When we have nice bùbá and ìró,

Àmọ́ àkísà lẹ̀yín yàn láàyò.
But you chose to wear rags.

Gbogbo ibi la ti ń bá ọ, bíi ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀
You are everywhere just like the air

Ìwọ lónìí, ìwọ lánàá bí kún apọkọj
It is you today, you tomorrow

Wàá gbé dúdú, gbé pupa,
You date dark and fair skinned,

Bó ń gbé kúkúrú lò ń gbé gíga
As you date short men, so you date tall ones

Àti ọ̀dọ́ àt’ọkọ ilé, déédé ni
Boys and married men, its okay

Ṣé kò kí ń rẹ̀ ọ́ ni? Ó rẹ̀ mí tì, é le è rẹ̀ mí lo fi ń e
Don't you get tired? Never, you never get tired

Àtolátọ̀sí, àtoní wárápá, gbogbo wọn ló ń ebẹ̀,
Even patients of urinary infection, and epilepsy come close,

ò kọ̀ kan, gbogbo ayé ní í gbé e sẹ́nu, 
You don't mind, the world puts its mouth,

 yàtọ̀ sí síbí ilé ìjun
Not different from spoon of a restaurant

Àlàpà tó dnu ílẹ̀ran oríi ní í fi bẹ̀ e ‘lé
Broken wall that is open, any animal lives in it

Tára bá bájẹ́ talára ní í dà, bí ọ̀rọ̀ àgbà,
When the body get spoil, only the owner feels it

Ṣọ́ ọ e ọmọge fácitì, ìwọ ọmọ ilé ìwé gíga  ṣọ́ra e
Be careful, pretty university girl, you high school girl 


Alágmọ ti bímọ, àìmọ́jó dọwọ́ọ yín .
The masquerade agmọ has given birth to a child, it is left for the child to learn to dance.

What do you think about the ewì?

And don't forget to subscribe to this blog ;).

Visit YOUTUBE for the audio version.


Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.

Friday, November 8, 2013

Ará Èkó ò mọyì ará oko - HOW?

When i hear the saying "ará Èkó ò mọyì ará oko" i usually wonder, what does the òwe, ará Èkó ò mọyì ará oko mean? What would have inspired our fathers to make such a statement?


Máà kán jú; don't be in a haste, this is the topic ; orí-ọ̀rọ̀ of discussion.

Literally, the statement implies that the farm men; ará oko see themselves as valuable than the ará Èkócity people think. They belief they are more important (ní-ìwúlò) and should be accorded regards for their efforts which is nothing other than food production.


Ará means people, relatives, relations, family, friend. Whereas, Èkó is a local parlance for Lagos while oko means farm.



"Ará Èkó ò mọyì ará oko "


- the Lagos (urban) habitats no not the value of the villagers (rural people).  

Come to think of it, the above statement is true - tòótọ́ lọ̀rọ̀ Yorùbá yìí, ẹsin ọ̀rọ̀ ńlá sì ni pẹ̀lú. 

The proverb has so many meaning ascribed to it. First, most of the raw materials needed for human survival all comes from the land; farm which is cultivated by someone. 



Bí àgbẹ̀ bá jí á mú kọ́
(the farmer wakes up, picks his hoe)

Farmers wake up lóòórọ̀ kùtù from sleep many times as early as 5 am (aago márùn-ún ìdájí), head to farmland to commence the days work - láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀. A journey which may take over an hour or more for the olóko; farm owner gets to the farmland; oko.

If the farm is an Ẹgàn (land that have not been used/cleared for cultivation in a long time), the strong farmer needs to cut down the bush all by himself (fún ra rẹ̀), hire an alágbàro who is paid for the job or clears the land together with his team of farmers whom he has asked for assistance on his new farm. This assistance is called Àáró; clearing of the farm, which farmers do to help themselves on the farm. Portion of crops from the land goes to them at harvest.



Bí àgbẹ̀ bá ro oko ẹ̀gan tán - After clearing the bush, and the seeds; irúgbìn have been prepared, the farmers make beds/ridges; ebè (ebè àkyíká tàbí ebè olọ́gr) before sowing of the seeds (gbin èso/irúgbìn)


Often times - nígbà gbogbo, ìgbẹ́ màálù; cow dung, human feces; imí èèyàn, poultry wastes; imí adì are materials used as manure (ajílẹ̀/ajẹ́lẹ̀) on the farm.


Now that the crops have been planted, the farmer must wet the crops regularly; ní gbà gbogbo if the land is not an àbàtá/àkùrọ́; mired soil. The àgbẹ̀ waters; (wọ́n omi sì) the plants day-by-day, clear the weed; koríko and also watches out for pests, insects kòkòrò that might be of threat to the crops. 


The ará-oko oníṣẹ́ akíkanjú (deligent farmer) works day-to-day (jọ́-sọ́jọ́), month-to-month (où-dóù) as well as year-to-year (dún-mọ́dún), in rain and dry; nínú òjò ńnú ẹ̀rùn ensuring that his great work (iṣẹ́ takuntakun) to bring oúnjẹ́food to the table of the ará Èkó is brought to fruition (di múmú s). 


Yet, ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ ; many farmers lost their apá àti ẹ̀sẹ̀ - limbs due to farm work - iṣẹ́ oko, cutlass; àdá, thorns and prickles; ẹ̀gún on the oko has injured farmers, scorpions; àkééke, snakes - ejò has bitten them many a times. pẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè -Thank God for the leaves; ewé found on farm came to the rescue by tranquilizing the venom or poison - oró of the serpents (àwn ewé kan wà tí a ma ńgbo sójú gbò bí ejò tàbí àkééke bá bu ni jẹ). 


Many ará -oko did not wait to tell the story; ìtàn of what happened in the wood - aginjù, wild beasts (ranko búburú) devoured (pa) them. 


Truly, ará -oko tó láti gbé gẹ̀gẹ̀; they deserve to be adored, many àgbẹ̀ as well as ọdẹ lost their lives - pàdánù ẹ̀mí while foraging the forest all for the survival of other men like them.


Before the scarecrow "aokopẹ́" used to ward off - lé birds; ẹy that feeds on crops on the oko, the great àgbẹ̀  aroko bọ́dún dé; he who farms year to year, does more work in ensuring that no useless ẹy  feed on his hard labour  (iṣẹ́-ipá). He has to stay back on the oko warding off birds. He sleeps - sùn in the ahéré; farm house leaving the night danger behind his mind; láì ro ewu alẹ́.

Its time for harvest; ìkórè, the crops are packed into the basket; apẹ̀rẹ̀, sackàpò to be transported to the jà market: city.


That is not all, for processed foods like gaàrí, fùfú and other Yorùbá staple made from cassava; pákí/ẹ̀gẹ́/gbágùdá, it takes more days to get to the jà and finally city. But its a pity its no longer so, cassava harvested today gets to the market tomorrow or next and this is dangerous to human health

Here, is the process to make gbágùdá/pákí into gaàrí or fùfú :-


Orítẹ̀
  • Harvest the gbágùdá/pákí/ẹ̀gẹ́
  • Bó pákí ; Peel the casssava
  • Fọ ẹ̀gẹ́ kí o gé e wẹ́wẹ́- wash the ẹ̀gẹ́ and chop into 2/3 pieces (for gaàrí  grate the cassava after wash. Soak cassava in water for a 3-5 days for fùfú (rẹ pákí fún ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-ún, láti y igi àárín rẹ̀ jáde)
  • Sẹ́ ẹ kí o dàá sínú àpò tó mọ́ kan, kí o so ó pẹ̀lú ìgege)sieve, put the pákí into a sack and tie the sack with ìgege (a stick/iron object ).
  • Put the sack on the orítẹ̀/atẹ̀/irin kórokóro and let it stay for a week to extract the bad starchy water.
  • After a week, bring down the sack and fùfú is ready.
  • Fry the gaàrí  in ap; large pot for frying ẹ̀gẹ́
  • Pour in apẹ̀rẹ̀ or àpò
 "torí ọ̀yà ni  Ọlọ́run fi dá eèsún, torí ará-ilé ni Ọlọ́run fi dá  ará-oko" 

The above òwe buttress the fact that the ará-oko are created by Elẹ́dùmarè to provide food; pèse oúnj for human survival; láti so ẹ̀mí ènìyàn ró


Without the ará-oko what will the city ará-ilé feed on? Game; ẹran-ìgbẹ́, popularly called bush-meat, how will the rich man in the city be able to buy if someone in the oko did not hunt it?


Kí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ iẹ́ ọ̀gbìtó ó dé ni àwọn a oko ti ńṣiẹ́ oko -  ará-oko have been providing food to the people from near and far even before the invention of modern farming utensils.




Ará Èkó ò mọyì ará oko

If you don't know, the àgbẹ̀ abìrokokùà/ará-oko are actually called ará oko not because they live in abúlé; villages but because they sleepover on the farm - oko, under the àtíbàbà; farm house and only come home either monthly; oooù, quarterly; ìdákúrékú or yearly; lọ́dọọdúnThey are the òkú-ìgbẹ́ who live on the farm.

Even with all the stress; ìdààmú and hard labour, the a oko stay healthy, feed on roots and herbs; egbò, ewé, eat fresh day in day out, which keeps them alive, old but agile and strong.

Do you think the a oko deserves to be adored? As the proverb ará Èkó ò mọyì ará oko implies, do you think they deserve any value; iyì?



Yes, i think so. Let me know your view.


>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>


www.youtube.com/yobamoodua

Check out www.yobamoodua.org for more on Yorùbá education and information.