Subscribe Now: RSS feed

Friday, 21 March 2014

Ọpẹ́lọpẹ́ @twitter

Gba #tweet r àkọ́kọ́ níbi
Ọpẹ́lọpẹ́ @twitter, ọpẹ́lọpẹ́ ayélujára, ẹ̀rọ ayárabíàṣá ìgbàlódé tó ń gbọ́rọ̀káyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn. 
Kí lọ fẹ́ tí ò sí lóríi ayélujára. 

Ọpẹ́lọpẹ́ @twitter, lọ́wọ́ kan là ń mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ, ẹsẹ̀ kan náà ni gbogbo ayé  ń gbọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ki ṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé. 

Tẹ́lẹ̀, nígbà tí kò sí ayélujára, ẹni ò ní àpótí àfowólé ẹ̀rọ amóhùmáwòrán ilẹ̀ òkèèrè ò lè mọ ohun ń lọ lágbàáyé. Ìròhìn ìṣẹ̀lẹ̀ onírúurú ni à ń rí lóríi ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyée @twitter, ọpẹ́lọpẹ́ ayélujára. 

Àti pé, ààyè ṣí sílẹ̀ gbagada fún gbogbo ọmọ aráyé láti wà lóríi ayélujára. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń fi @twitter ṣe jẹunjẹun, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ oòjọ́ tí wọ́n fi ń gbé jẹ. 

Ọpẹ́lọpẹ́ @twitter, ọpẹ́lọpẹ́ ayélujára, èmi náà ò bá máti wà níbi.