Subscribe Now: RSS feed

Friday, 14 June 2013

Fi Èdè Yorùbá Kọ́ Ọmọọ̀ Rẹ (Teach Your Child Yorùbá Language)

Lánàá òde yìí, ẹgbẹ́ agbóhùnsafẹ́fẹ́ lédè Yoòbá pé ìpàdé àpérò, ìjíròrò ìṣe, àṣà Yorùbá, orí ọ̀rọ̀ ìjókó náà kò sì kọjá ohun tí a lè ṣe, ọ̀nà tí a lè gbà gbé èdè àṣà, ìṣe ìbílẹ̀ wa lárugẹ. 


The Yoruba Broadcasters Association Lagos state organized a seminar on reviving the Yoruba language in our homes.


Ọ̀pọ̀ ọmọ Yoòbá àtàtà, àwọn lọ́balọ́ba, èèyàn jànkàn-jànkàn ló péjọ síbi ìpàdé yìí láti gbé àṣà baba-ńláa wa ga. Àwọn àgbàgbà bíi baba Ẹlẹ́buìbọn, ògbóntàgi ọ̀yàwòrán èré orí-ìtàgé Túndé Kìlání, olóyè Gàní Adams àti àwọn ọmọ Yorùbá réré lópéjú pésẹ̀. Wọ́n ṣa àwọn òbí láì yọ̀ alágbàtọ́ sílẹ̀ lábẹ ọ̀rọ̀, wọ́n wí fún wọn pé ó kúdíẹ̀káto kí ọmọ káàárọ̀-o-ò-jíire málè fọ èdè bàba rẹ̀. 


Various sons and daughters of Yoruba land were in attendance; Lai Mohammed, Tunde Kilani, Yemi Elebuibon, Gani Adams and others.


Ìwádí fi hàn pé bí ó ba e díẹ̀, èdè Yorùbá a pare, k'Èlédùà máj a ríi.  Lá ní láti fwọ́sowọ́pọ̀ wá nǹkan e kí èdè wa má báa gb bí i odò, kí a má gbàgbé orísun wa.

Researchers claim that in years to come, the Yoruba language will be extinct. We must therefore collectively endeavour not to let it die.

Àfi kọ́mọ Yoòbá máà f'èèbó bi ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀. Alàgbà Láì Mòhammẹ̀d ti ẹgbẹ́ òṣèlú ACN pàápàá gbà àwọn òbí nimọ̀ràn láti fi èdè, àṣà ìṣe ilé wa kọ́, tọ́ àti wo àwọn èwe wa torí àwọn ọmọ wọ̀nyí ni yí ó kù nílé bí àgbà ilé bá filẹ̀ ṣaṣọ bọra, àwọn ni kò ní jẹ́ kílé dahoro. 


Instead of speaking more in Yoruba, our children speaks English than the former, whereas some don't even know how to speak because their parents do not teach or speak with them in Yoruba language. Chief Lai Mohammed implored parents to speak and teach the Yoruba culture to their wards.

Torí náà, ó ṣe kókó, ó ṣe pàtàkì kí àwọn ọmọ àti àrọ́mọdọ́mọ wa gbọ́ Yoòbá kí èdè baba ńláa wa Oòduà, Ọ̀rànmíyàn, àti àwọn àgbàgbà ilẹ̀ kú-oótù-oòjíire má bá à di ohun ìgbàkánnì, ohun ìgbàgbé, òyìnbó là á ńtẹ̀lé gọ̀ṣúgọ̀ṣú a gbàgbé pé a kí í ṣe òyìnbó a si le dabi won. 

Chinua Achebe has said, "my people no longer act as one..." why? because things has fallen apart, we all want to act and be like the whites neglecting the real-self whereas this is not possible. We should stop following them like zombies.

Ọ̀rọ̀ yìí kànwá gbògbògbò, ó kandandan kí ọmọ Odùduà mọ òwe, ìṣe, iṣẹ́ àti gbogbo nǹkan tó rọ̀mọ́ àṣà Yorùbá. A kúkú ní báwọn wí bíkòṣe àwọn òyìnbó ọlọ́gbọ́n àrékéreké tí ó sa gbogbo ipá láti pa ìran Yorùbá rẹ́ lórílẹ̀-èdè ayé. Àti pé, ó yẹ kí ilé-ìwé máà fi èdè àbínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ́ọ̀ọ́ láti jẹ́léósimi alákọ̀bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì, èyí á jẹ́ kí akẹ́kọ́ọ̀ọ́ mọ ìgbéayée wọn gẹ́gẹ́ bí alágbẹ̀dẹ ṣe mọ Ògún.  

Brethen, it is our responsibility as bonafide sons and daughters of Oduduwa to train our child in the way of the Yoruba culture and tradition. The educational curriculum should accommodate teaching all subjects, courses in Yoruba language from elementary to higher institution.

Toò, tèmi tìrẹ, m Oòduà tkàntkàn, ìṣẹ̀ṣe làgbà, ọmọàlè ní ń f'ọwọ́ òsì júwe ilé Bàbá rẹ̀, kí Yorùbá má bàá kú dọwọ́ wa ooooo!!!  

To this end, tradition is key and paramount, only a bastard points to his father house with his left hand. True sons of Oòduà, the onus lie on all Yoruba to keep the Yoruba heritage alive for the future generation.


Do you understand Yoruba? Do you speak it well? See this little girl speaking Yoruba > Fi Èdè Yorùbá Kọ́ Ọmọọ̀ Rẹ

Click and subscribe - www.youtube.com/yobamoodua 


eun :)